عرض المقال :Knowledge of Mirza Ghulam Ahmad Qadiani
  الصفحة الرئيسية » مـقـالات الموقـــع » كشف البلية بفضح الأحمدية » Non - Arabic Articles » Yoruba

اسم المقال : Knowledge of Mirza Ghulam Ahmad Qadiani
كاتب المقال: webmaster

BISMILLAH AL-REHMAN AL-RAHEEM

Tani alabosi to eni tio hun iro nipa Allah abi so pe oun gba oro wa beeni a ko fi nnkankan ranse si – Al-Quran

Imo Ti Mirza

Adapa Iro , Ati Etan

lati owo Dr. Rashid

Montaigne sope lati je opuro to lagbara, enia lati je eni tiki gbagbe ikan rara, ati pe o ni lati mani iranti gbogbo awon ikan ti o ti so tele. O de tun ni lati ni ogbon to ye kooro. Kii se awon eeri ni kan ni opuro nilo bi ko otun ni lo na lati ko awon idi ti ko jo arawon papo soju kan. Ise nla ni eleyi.

“Enia kan ko le ni iranti to muna titi, lati je opuro to yege” Abraham Lincon.

Mirza Ghulam Qadiani, Oludasile ijo Ahmadiyya, da adapa iro pe ojise Allah ni oun , Olugbara to se ladehun ati imam Mahdi, ohun ni kan ni gbogbo eleyi ati awon nnkan miran to pe rare.Oni ohun ri ibani soro Allah gbaati wipe Oluwa ti ko oun ni gbogbo ikan lai lo eda kankan.

“Ati pe bi mo se gbagbo ninu iwe tia fi ranse si mi , mo si le duro ni Kaaba lati bura pe oun tia fi ranse si mi ni oro Oluwa kan naa to ranse si Musa ati jesu ati Anobi Muhammad sala lahu alahi wasallam” (aik ghaltee kaa izala p.6 roo hani khazain vol. 18p210).

“ Mo fi Allah bura pe moni igbagbo pelu ise iranse simi gegebi igbagbo mi si Alikurani ati awon iwe miran lati odo Oluwa, ati gegebi mo se mu kurani mimo ni iwe ododo to daju ni mi se gba oun ti a sokale funmi gbo pe oro Oluwa ni “(HaqeeqatulWahi p.211,Rohani Khazian vol 22 p.220).

Nitorina a ni eri lati lero pe oun kohun ti Mirza Ghulam ba ti so abi ko sinu awon iwe re jeoun to waye lati odo Allah, torina ko si oro ibere asise tabi iro tabi adapo iro. Mirza sope:

“Oluwa ki fimi sinu asise , koda ni iseju kan , Osi da abo bomi ni gbogbo igba koda lowo asetani”. ( Nurul Haq, Roohani Hkazian vol. 8 p.372)

“ Gbogbo ohun ti mo ba so , mo so pelu iyon da Re (Allah) , mi o ti se ohun kankan lati inu okan mi wa atipe mi o da adapa iro lori Oluwa mi.” (Mawahibur rehman p3 Roohan Khazain vol. 19p .221).

“ wa ma unteqo unil hawa in howa illa wahun yooha” Ko ki so ikankan lati owo ara re bikose ohun to ba gbo lati odo Oluwa” Arabad’een no. 3, Roohani Khazain vol 17, p.426-427).

Awon oro Mirza Ghulam Ahmed wonyi fi oju han gbogbo oun to se tabi so,gbogbo ohun to ko sinu iwe bi metalelogorin (83) ati papa oro ifi ranse (wa’yi ) ti won pe ni Tadhkirah ati idi iwe meta (3) to ti polowo wa lati odo Oluwa , gegebi Ghulam Ahmad ti wi , o dami loju pe awon Ahmadis/Qadiani/Lahori a tele mi lori eri yii.

Nibayi, ti asise tabi iro ba wa ninu awon iwe wonyi, tani ki a pe ? Nje a le so pe lati owo Oluwa nibi (Aigbodo)? A ya fi pe Oluwa ti puro lati da yeye re sile lodo awon alatako re.

Nigba to jasi pe oluwa ko le se asise tabi puro, alaye miran tio o si se nipe gbogbo oro ifiranse, je lati odo satani sodo Mirza Ghulam ni ipase “ELI” “ tiche tiche khairaatee ; Mo fi si owo eyin ti o kawe yi lati se idajo to bah an si yin.

Ninu aawon oro ti nbo, ma mu awon apere adapa iro wa ati itukutu oro ododo ati iro to daju. Sugbon kin nto te siwaju, jowo ka oun ti Mirza Ghulam ni lati so nipa aladapa iro.

« Iro pipa ko kere si ipe ara eni ni ounti a ko je » (Arba’een no 3p.24 footnote, Roohaniu Khazam vol.17p,56 ,407)

« Eni ti a ba ni opuro ninu ikankan, ko leto ka gbogbo ninu awon ikan miran » (chashma-e maarifat p.222, roohani khazain vol.231)

Mirza Ghulam ti so ninu awon iwe re pe orisi meji ni ero isipaya okan inu wa.

(1) ero isipaya okan ni oro ti Oluwa (Ilham Rohmani)

(2) ero isipaya okan oro ti satani (Ilhan Shaitan)

Ododo ni iba ni soro ati okan ti Oluwa. Iro ni opolopo ero okan satani, sugbon yoo ma je ododo ni gba miran lati soni nu fun era nla ti tie.Atigba oro ati iba ni soro ti Mirza Ghulam yoo ma je kika si ara orufe ona yi.

Ma bere oro yi lati ibi iwe Mirza Ghulam to ni se pelu itan eyi ti enikeni le se iwadi lori e. Ko si alaye lo titi, ida ikeji awon oro to rorun la ti gbo agboye.

« Awon onipitan mo wipe omokunrin mokanla ni abi nile re(Anabi Muhammed SAW) gbogbo won ni won si ku ». (Chashma em a’arifat p.p286, Roohani Khazaain vol 23p.299 )

« woo, omobinrin ,mejila ni abi nile Anabi Oluwa (saw),ko wi pe won ko se bi omokunrin » (Malfoozat vol.6 p. 57)

“Ojise mi mo ko si ni anfaani atiko ede abinibi lati odo awon obi re to ripe lati omo osu mefa ni awon mejeeji ti ku » .(Ayani-usosulh p 150, roohani Khazian vol. p.396 footnote).

E je ka wo iwe itan igbesi aye Anabi wa Muhammad SAW. O ni omokunrin merin ati omobirin merin. Ko si eyi ti o so pe ojise mimo ni omobirin mejila tabi omokunrin mokanla, Baba Anabi ku saaju ki ato bi Anabi, iya re si jade laye pelu nigba ti Anabi di omodun mefa (6). Ni bo wa ni Mirza Ghulam ti ri eri fun oro to so wonyi?

“Gbogbo oun ti mo ti so, mo so pelu iyanda Oluwa ni atipe mi o se Ounkoun lati owo ara mi, emi ko da adapa iro mo Oluwa mi” (Mawahibur Rehman p.3 , Roohani Khazain vol. 19p 221).

Bayi, tani “Olohun” yii ti o pa iro yii , ti o si yeye ojise re? Nje o wa sese pe awon oro ti esu ni eleyi ? Tabi pe oro daru mo Mirza loju ni ? Sugbon Oluwa ko fi Mirza sile sinu asise ni iseju aaya bo ti leri.( “ Lai se iyemeji, Oluwa ko ko mi sile ninu asise ni iseju kaan ; on so mi ni asise, beeni on dabobo mi kuro ni bi awon ona ti esu).

(Nurul Haq last page, Roohani Khazain vol. 8 p.372)

Ona yowu ki iba ni soro gba wa, enia yowu ko wa nidi oro yi , eyi to daju nipe iba ni soro yii kii se ti Oluwa Oba Allah Sugbon lati odo esu ni. Mo pe gbogboAhmadi, ki won ronu jinle si eleyi.

Wassalam.

Dr. Syed Rashid Ali

Anti Ahmadiyya Movement in Islam

Dr. SEYD RASHID ALI

P.O. BOX 11560

DIBBA Al FUJAIRAH, United Arab Emirates

Fax : 00971 9 2 442846

rayed@emirates.net.ae

http://alhafeez.org/rashid/

اضيف بواسطة :   admin       رتبته (   الادارة )
التقييم: 0 /5 ( 0 صوت )

تاريخ الاضافة: 26-11-2009

الزوار: 2633


المقالات المتشابهة
جديد قسم مـقـالات الموقـــع
القائمة الرئيسية
البحث
البحث في
القائمة البريدية

اشتراك

الغاء الاشتراك